Onídájọ́ 20:47-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rámónù, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin.

48. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì padà sí àwọn ìlú Bẹ́ńjámínì wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.

Onídájọ́ 20