Onídájọ́ 20:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.

23. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ wọ́n sunkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

24. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì.

25. Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Bẹ́ńjámínì jáde sí wọn láti Gíbíà, láti dojú kọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán (18,000) ọkùnrin Ísírẹ́lì, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

Onídájọ́ 20