Onídájọ́ 18:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dánì yípadà wọ́n sì bi Míkà pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”

24. Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ”

25. Àwọn ọkùnrin Dánì náà dáhùn pé, “Má se bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.”

Onídájọ́ 18