22. Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Míkà, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbégbé Míkà kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dánì bá.
23. Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dánì yípadà wọ́n sì bi Míkà pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”
24. Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ”
25. Àwọn ọkùnrin Dánì náà dáhùn pé, “Má se bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.”