1. Ní ọjọ́ kan Sámúsónì lọ sí Gásà níbi tí ó ti rí obìnrin aṣẹ́wó kan. Ó wọlé tọ̀ ọ́ láti ṣun ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ náà.
2. Àwọn ará Gásà sì gbọ́ wí pé, “Sámúsónì wà níbí.” Wọ́n sì yí agbégbé náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu bodè ìlú náà. Wọn kò mira ní gbogbo òrú náà pé ní “àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á”
3. Ṣùgbọ́n Sámúsónì sùn níbẹ̀ di àárin ọ̀gànjọ́ (èyí nì di agogo méjìlá òru). Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hébírónì.