1. Àwọn ọkùnrin Éfúráímù pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí Sáfónì, wọ́n sì bi Jẹ́fítà pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ámónì jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò ṣun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”
2. Jẹ́fítà dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ámórì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn.
3. Nígbà tí mo ríi pé ẹ̀yin kò ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́, mo fi ẹ̀mi mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ámónì jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, Èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”