Onídájọ́ 11:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Jẹ́fità sì tẹ̀lé àwọn olóyè Gílíádì lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jẹ́fità sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mísípà.

12. Jẹ́fítà sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ámónì pé, “Kí ni ẹ̀ṣùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?”

13. Ọba àwọn Ámónì dá àwọn oníṣẹ́ Jẹ́fità lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ti Éjíbítì wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Ánónì dé Jábókù, àní dé Jọ́dánì, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”

Onídájọ́ 11