Nọ́ḿbà 8:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Mú kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa.

14. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Léfì sọ́tọ̀, kúrò láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ tèmi.

15. “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.

16. Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátapáta nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkunrin gbogbo Ísírẹ́lì.

Nọ́ḿbà 8