Nọ́ḿbà 7:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

15. Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

16. Akọ ewurẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,

17. Màlúù méjì, àgbò márùn ún, akọ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Násónì ọmọ Ámínádábù.

Nọ́ḿbà 7