Nọ́ḿbà 36:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”

10. Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣẹ́lófẹ́hádì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

11. Nítorí pé a gbé Málà, Tírísà, Hógílà, Mílíkà, àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Ṣélófẹ́hádì ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.

Nọ́ḿbà 36