Nọ́ḿbà 35:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jọ́dánì, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kénánì tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí.

15. Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀.

16. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pá, apànìyàn náà.

Nọ́ḿbà 35