Nọ́ḿbà 32:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhínyìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa.

17. Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣááju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdábòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà.

18. A kì yóò padà sí ilẹ̀ wa láì ṣe pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gba ogún wọn.

Nọ́ḿbà 32