Nọ́ḿbà 31:39-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún, ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, (30,500) tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta; (61).

40. Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n. (32)

41. Mósè fi ìdá náà fún Élíásárì, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

42. Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Mósè yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun.

43. (Ààbọ̀ tí àwọn ará ìlú sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàdọ́sàn-án ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn,

44. pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) màlúù

45. tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (30,500)

Nọ́ḿbà 31