Nọ́ḿbà 31:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, tanńganran àti òjé.

23. Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.

24. Ní ọjọ́ kéje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”

25. Olúwa sọ fún Mósè pé,

26. “Ìwọ àti Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbékùn.

Nọ́ḿbà 31