1. Ìwọ̀nyí ni ìdílé Árónì àti Mósè ní ìgbà tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ní òkè Sínáì.
2. Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀nyí, Nádábù ni àkọ́bí, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.
3. Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀n yìí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.