4. àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀dọ́ àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn méje.
5. Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín.
6. Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.
7. “ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpèjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó ṣẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.