17. “ ‘Àti ní ijọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rúbọ.
18. Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
19. Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ mímu.
20. “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù.