Nọ́ḿbà 22:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Bálámù wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”

21. Bálámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù.

22. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, áńgẹ́lì Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Bálámù ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

Nọ́ḿbà 22