2. Nísinsìnyìí Bálákì ọmọ Sípórì rí gbogbo ohun tí àwọn Ísírẹ́lì ti ṣe sí àwọn ará Ámórì,
3. ẹ̀rù sì ba Móábù nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Móábù kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
4. Móábù sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì pé, “Nísinsìnyìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Bálákì ọmọ Ṣípórì, tí ó jẹ́ ọba Móábù nígbà náà,