Nọ́ḿbà 21:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. “Iná jáde láti Hésíbónì,ọ̀wọ́ iná láti Ṣíhónì.Ó jó Árì àti Móábù run,àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Ánónì.

29. Ègbé ní fún ọ, ìwọ Móábù!Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kémósì!Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀san àti ọmọ rẹ̀ obìnringẹ́gẹ bí ìgbékùn fún Ṣíhónì ọba àwọn Ámórì.

30. “Ṣùgbọ́n ati bì wọ́n ṣubú;A ti pa wọ́n run títí dé Díbónì.A sì ti run wọ́n títí dé Nófà, tí ó sì fí dé Médébà.”

Nọ́ḿbà 21