Nọ́ḿbà 17:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Mósè sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.

8. Ó sì se ní ọjọ́ kéjì Mósè wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Árónì, tí ó dúró fún ẹ̀yà Léfì, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó ruwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso jíjẹ.

9. Nígbà náà ni Mósè kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.

Nọ́ḿbà 17