Nọ́ḿbà 16:47-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Árónì ṣe bí Mósè ti wí, ó sáré lọ sí àárin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn, ṣùgbọ́n Árónì fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.

48. Ó dúró láàrin àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dúró.

49. Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti pa ẹgbàá méje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kórà.

50. Árónì padà tọ Mósè lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpade nítorí pé àjàkálẹ̀-àrùn náà ti dúró.

Nọ́ḿbà 16