Nehemáyà 9:22-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. “Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Ṣíhónì aráa Hésíbónì àti ilẹ̀ ógù ọba Báṣánì.

23. Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀

24. Àwọn ọmọ wọn wọ inú un rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn aráa Kénánì, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájúu wọn; ó fi àwọn aráa Kénánì lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n.

25. Wọ́n gba àwọn ìlú olódì àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kàǹga tí a ti gbẹ́, awọn ọgbà àjàrà, awọn ọgbà ólífì àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáadáa; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ

26. “Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì ṣe ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.

27. Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀taa wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn.

28. “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì tún ṣe búburú lójùu rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀ta kí wọ́n lè jọba lóríi wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.

Nehemáyà 9