Nehemáyà 6:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́láa Júdà ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tòbáyà, èsì láti ọ̀dọ̀ Tòbáyà sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn.

18. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júdà ti mulẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekenáyà ọmọ Árà (Ṣáńbálátì fẹ́ ọmọ Ṣekenáyà) ọmọ rẹ̀ Jéhóhánánì sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámì ọmọ Bérékíyà

19. ṣíwájú sí í, wọ́n túnbọ̀ ń ròyìn iṣẹ́ rere rẹ̀ fún mi, wọ́n sì ń sọ ohun tí mo sọ fún-un. Tòbáyà sì ń kọ àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti dẹ́rù bà mí.

Nehemáyà 6