Nehemáyà 4:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ pé àwa ti mọ ọ̀tá wọn àti wí pé Ọlọ́run ti bàájẹ́, gbogbo wa padà sí ibi odi, ẹnìkọ̀ọ̀kan sí ibi iṣẹ́ tirẹ̀.

16. Láti ọjọ́ náà lọ, ìdajì àwọn ènìyàn ń ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn ìdajì tó kù múra pẹ̀lú ọ̀kọ̀, àṣà, ọrun àti ìhámọ́ra. Àwọn ìjòyè sì pín ara wọn ṣẹ́yìn in gbogbo ènìyàn Júdà.

17. Àwọn ẹni tí ó ń mọ odi. Àwọn tí ń ru àwọn ohun èlò ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọwọ́ kan, wọ́n sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà mú,

18. olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idàa wọn sí ẹ̀gbẹ́ẹ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lúù mi.

19. Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tó kù pé, “Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi.

20. Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!”

21. Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ.

Nehemáyà 4