Nehemáyà 2:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní oṣù Níṣánì (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún-un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, Ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájúu rẹ̀.

2. Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn”Ẹ̀rù bà mí gidigidi,

3. Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! È é ṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”

Nehemáyà 2