Nehemáyà 12:46-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. Ní ọjọ́ pípẹ́ ṣẹ́yìn ní ìgbà Dáfídì àti Áṣáfì, ni àwọn atọ́nisọ́nà, ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.

47. Nítorí náà ní ìgbà ayé Ṣérúbábélì àti Nehemáyà, gbogbo Ísírẹ́lì ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn ṣọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Léfì tó kù àwọn ọmọ Léfì náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Árónì sọ́tọ̀ fún wọn.

Nehemáyà 12