6. “Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.“Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;kí ìtìjú má ṣe le bá wa”
7. Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jákọ́bù:“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nì wọ̀nyí?”“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rerefún ẹni tí ń rìn déédé bí?
8. Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìdebí ọ̀tá sí mi.Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.