6. “Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.“Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;kí ìtìjú má ṣe le bá wa”
7. Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jákọ́bù:“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nì wọ̀nyí?”“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rerefún ẹni tí ń rìn déédé bí?
8. Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìdebí ọ̀tá sí mi.Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
9. Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mikúrò nínú ilé ayọ̀ wọn,ẹ̀yin sì ti gba ògo mi,kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.
10. Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ!Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín,nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́yóò pa yín run,àní ìparun kíkorò.