Mátíù 8:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà tí Jésù sì wọ̀ Kápánámù, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.

6. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ àrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”

7. Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”

8. Balógun ọ̀rún náà dahùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.

Mátíù 8