Mátíù 5:40-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Bí ẹnì kan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.

41. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì.

42. Fi fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó fẹ́ ya láti lọ́wọ́ rẹ.

43. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Fẹ́ràn aládúgbo rẹ, kí ìwọ sì kórírà ọ̀ta rẹ̀.’

44. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀ta yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín,

Mátíù 5