Mátíù 4:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Jésù sì rin káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba ọ̀run. ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn gbogbo àti àìsàn láàrin gbogbo ènìyàn.

24. Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Síríà ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú àrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

25. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì, Dékápólì, Jerúsálémù, Jùdíà, àti láti òkè odò Jọ́dánì sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Mátíù 4