Mátíù 28:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrin àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.

16. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Gálílì ní orí òkè níbi tí Jésù sọ pé wọn yóò ti rí òun.

17. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n forí balẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyè méjì bóyá Jésù ni tàbí òun kọ́.

18. Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi.

Mátíù 28