27. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun baálẹ̀ mú Jésù lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í
28. Wọ́n tú Jésù sì ìhòòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ láṣọ òdòdó,
29. Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù!”
30. Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án mọ́ ọn lórí.