Mátíù 22:31-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé:

32. ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”

33. Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.

34. Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, àwọn Farisí pé ara wọn jọ.

Mátíù 22