Mátíù 2:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nítorí náà, Ó sì dìde, ó gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Ákílọ́sì ni ó ń jọba ní Jùdíà ní ipò Hẹ́rọ́dù baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Gálílì lọ,

23. ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Násárẹ́tì. Nígbà náà ni èyí tí a sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Násárẹ́tì.”

Mátíù 2