17. Jésù dá a lóhùn pé, “È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”
18. Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jésù dáhùn pé, “ ‘Má ṣe pànìyàn, má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe ìjẹ̀rìí èké,
19. bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”
20. Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe?”
21. Jésù wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”
22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
23. Nígbà náà, ní Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.”