9. Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?
10. Ẹ kò sì tún rántí ìsù méje tí mo fi bọ́ ẹgbààjì (4,000) ènìyàn àti iye àjẹkù tí ẹ kó jọ?
11. È é ha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti búrẹ́dì? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ti Sadusí.”
12. Nígbà náà ni ó ṣẹ̀sẹ̀ wá yé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyè sára, bí kò se tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti Sadusí.