Mátíù 13:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárin ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa.

8. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rún, òmiràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ó ti gbìn.

9. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èé ṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”

11. Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.

12. Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà.

13. Ìdí nì yìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:“Ní ti rírí, wọn kò rí;ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.

Mátíù 13