Mátíù 13:48-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

48. Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù.

49. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn ańgẹ́lì yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo,

50. Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

51. Jésù bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”

Mátíù 13