Mátíù 12:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ìkejì.

14. Síbẹ̀ àwọn Farisí jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un bí wọn yóò ṣe pa Jésù.

15. Ṣùgbọ́n Jésù mọ, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.

16. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ẹni ti òun jẹ́.

Mátíù 12