Mátíù 11:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ.

12. Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.

13. Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.

Mátíù 11