Mátíù 10:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà.

15. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sódómù àti Gòmórà ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.

16. Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrin ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.

Mátíù 10