13. “Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.“Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, ‘Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ?’
14. “Ẹ̀yín ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ ogun?
15. Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún Ní otitọ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Olúwa wò ni a dá sí.’ ”