Málákì 2:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,” ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “bẹ́ẹ̀ ni mo kóríra kí èníyàn máa fi ipá bó ara rẹ̀ àti pẹ̀lú asọ rẹ̀,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.Nítorí náà ẹ sọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má se hùwà ẹ̀tàn.

17. Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yin dá Olúwa ní agara.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèré pé, “Nínú kín ni àwa fi dá a lágara?”Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, “Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú Olúwa, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,” tabi “Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà?”

Málákì 2