Máàkù 3:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló yí i ká, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ kàn án.

11. Ìgbàkúùgbà tí àwọn tí ó kún fún ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú gán-án ní rẹ̀, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn-rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”

12. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.

Máàkù 3