1. Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Màríà Magidalénì àti Sálómì àti Màríà ìyá Jákọ́bù àti Sálómè mú òróro olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jésù lára.
2. Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, wọ́n wá sí ibi ibojì nigbà tí òòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ,
3. wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò lẹ́nu ibojì fún wa?”