Máàkù 13:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí Jésù ti ń jáde láti inú tẹ́ḿpìlì ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”

2. Jésù dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

3. Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé,

Máàkù 13