Máàkù 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ síí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan dá oko àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yì i ká, ó sì gbẹ́ ihò níbi tí omi yóò ti máa jáde fún ìtọ́jú ohun ọ̀gbìn. Níkẹyìn, ó gbé oko fún àwọn olùtọ́jú, ó sì lọ ìrìnàjò tí ó jìnnà.

2. Lákókò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn tí ń tọ́jú oko tí ó fi sílẹ̀, láti gba ìpín tirẹ̀ wá nínú ohun ọ̀gbìn oko náà.

3. Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọnnnì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

Máàkù 12