15. Mo ń sọ òótọ́ fún un yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti mọ̀, pé, ẹni tí kò bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bi ọmọ kékeré, a kì yóò fún un láàyè láti wọ ìjọba rẹ̀.”
16. Nígbà náà, Jésù gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.
17. Bí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò kan, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnipẹ̀kun?”
18. Jésù béèrè pé, Arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere.
19. Ìwọ mọ àwọn òfin bí i: Má ṣe pànìyàn, má ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe purọ́, má ṣe rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”
20. Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”